A ku ipalemo odun,odun yo ba wa layo ati alafia.Odun rere ni yo je fun olukuluku wa,ilu wa aroju araye.Iran yoruba ko ni paarun.Hu hu,kini ka se bi gbogbo re se nlo bayin.Oro ilu wa nfe adura gidigidi,e je ka pawopo jo pa.

Kila tun le se,a ko le ma wo bayi,kini ka se?

Fun awa ti a si ranti yoruba ti won ko wa ni ilewe alakobere,eleyi je okan laara ohun ti o nshi wa lori ti a ba ka ni igba yen,e je ka fi ko awon omo wa na.E je ki a fin awon ohun yoruba towulo yi lo awon omo wa leti,aye ti ndi nkan miran,ki apada si ese aro.Eyin je itumo re ni ede geest ti ojogbon Quansy Salako se fun awon omo wa oke okun.

ISÉ NI ÒÒGÙN ÌSÉ........Work is the antidote for poverty
MÚRA SÍ ISÉ RE ÒRÉÈ MI.......Work hard, my friend
ISÉ NI A FI Í DI ENI GIGA.......work is used to elevate one in respect and importance (Aspiring to higher height is fully dependent on hard work)
BÍ A KÒ BÁ RÉNI FÈYÌN TÌ, BÍ ÒLE LÀ Á RÍ;......if we do not have anyone to lean on, we appear indolent
BÍ A KO RÉNI GBÉKÈLÉ,.....if we do not have anyone to trust (we can depend on...)
À A TERA MÓ ISÉ ENI.....we simply work harder
ÌYÁ RE LÈ LÓWÓ LÓWÓ.....your mother may be wealthy
BÀBÁ SÌ LÈ LÉSIN LÉÈKÀN.....your father may have a ranch full of horses
BÍ O BÁ GBÓJÚ LÉ WON,........ if you depend on their riches alone
O TÉ TÁN NI MO SO FÚN O,......you may end up in disgrace, I tell you
OHUN TÍ A KÒ BA JÌYÀ FÚN,.....whatever gain one does not work hard to earn
KÌ Í LÈ TÓJÓ.....usually does not last
OHUN TÍ A BÁ FARA SISÉ FÚN,....whatever gain one works hard to earn
NÍ Í PÉ LÓWÓ ENI.....is the one that lasts in one's hands (while in ones possession)
APÁ LARÁ, ÌGÙNPÁ NÌYEKAN...... the arm is a relative, the elbow is a sibling
BÍ AYÉ N FÉ O LÓNÌÍ,....you may be loved by all today
BÍ O BÁ LÓWÓ LÓWÓ,......it is when you have money
NI WON Á MÁA FÉ O LÓLA......that they will love you tomorrow
TÀBÍ TÍ O BÁ WÀ NÍ IPÒ ÀTÀTÀ,.....or when you are in a high position
AYÉ Á YÉ O SÍ TÈRÍN-TÈRÍN,.....all will honor you with cheers and smiles
JÉ KÍ O DI ENI N RÁÁGÓ,....wait till you become poor or are struggling to get by
KÍ O RÍ BÁYÉ TI Í SÍMÚ SÍ O......and you will see how all grimace at you as they pass you by ÈKÓ SÌ TÚN N SONI Í DÒGÁ,.....education also elevates one in position
MÚRA KÍ O KÓ O DÁRADÁRA.....work hard to acquire good education
BÍ O SÌ RÍ ÒPÒ ÈNÌYÀN,.....and if you see a lot of people
TÍ WÓN N FI ÈKÓ SE ÈRÍN RÍN,....making education a laughing stock
DÁKUN MÁ SE FARA WÉ WON.....please do not emulate or keep their company
ÌYÀ N BÒ FÓMO TÍ KÒ GBÓN,.....suffering is lying in wait for an unserious kid
EKÚN N BE FÓMO TÓ N SÁ KIRI.......sorrow is in the reserve for a truant kid
MÁ FÒWÚRÒ SERÉ, ÒRÉÈ MI,.....do not play with your early years, my friend
MÚRA SÍSÉ, OJÓ N LO.....work harder, time and tide wait for no one.
Let’s pass it on to our children.


Oro ilu naijaria ti wa ti a wo ma le so.Kini a se fe pe ti olori orile ilu America ti o wa si ilu adu la wo fun igba akoko ni igba ti o de ori oye ti o je pe orile ede Ghana ni o lo.Awa nijaria ni igbagbo pe ilu wa ni o tobi julo ni ilu adu lawo sugbon sibesibe,ilu miran lo lo.

Kini ki a ti pe eleyi,nje ko se pe oro wa ti di nkan miran bayi? ape ra wa ni olori sugbon ko ja si nkankan bayi.Oro wa ti di hun bayi,kini ki a se?Lehin odun kan din ni adota,ako ti mo ohun ti a nse.
Eyin omo ilu olorire yin,e ba wa da soro yin,kinni ka a la se si ilo seyin to de ba orile ede yin?

O ga o,asiko ko duro de enikan.
Aye nlo a nto,igbawo lamu odun 2009 ti a di de idaji re
A pele ti akorin ilumoka ni-Micheal Jackson
Oluwa yoo dun awon ebi re ninu
Oro orilede wa yin ko ye ni mo
Eni rogbodiyan idibo,ola awon alajadula,kini a o ti se gbogbo eleyi si
Eyin otokulu ilu e ma wo wa niran
Awon iran bi ran wa yoo be re pe bawo lasese
Oro wa fe atunto nilu yi
Nibo lati si rin
E ba wa da soro yin

Sai Baba


Are Yar Adua ti yo oloselu nla ni,Ogbeni Kingibe kuru ninu ijoba re leyin to de laati ilu okeere.Ahunye hunye orisirisi loti lo nipa yiyo ara kunrin yin nitoripe Are ni o duro ti sai baba nigba ti o fe yan si ipo na nigbati egbe re ko jale lati fowosi yiyan re.Sugbon tinu ko ba gbo sunukun,inu ki baaje,awon esun lorisiri risi ni a ngbo pe o fa isele yin.A gbo pe o se inu meji pelu re ati pe oun lo koko gbe ipolongo iku re nipa ti o wa ni ile iwosan ni ilu okere ti ariwo fi ta.Se e le yi yio wa je ifaseyin fun ogbeni yi ni abi adaba tun ra mu loro re?

Oro di hun bayi o,nipa ailera olori orilede wa.Nje yio wa le se eto ilu bayi?Gbogbo wa la mo bi arun jejere se ma ndanu eniyan,atipe ise takun takun ni e ti yio se olori ma nse,o si gbodo wa ni alafia.Se ki se pe atun bo ninu ikan bo si omiran bayi?.Iyalenu lo je pe bi olorun ti bukun orilede yi to,a ko le to ilu wa daradara.Olori la je ninu iwo orun dusu sugbon gbogbo ihunwa si wa ko fi han rara,a kan je olori lasan ni,a ko le gbe adiye.Kinni ka se si?

Ipinnu

Mo se ileri pe emi yio ma se deede ni gbagede yin lati wakaati yin lo.Ede yoruba je ede kan ti a ko gbodo gbagbe,nitoripe a ni orisun ati pe ipa awon babalawa ko gbodo pee.Asa ati ise yoruba ko gbodo paare,yoruba a gbe wa o.E ku ilu yi,e ku bi gbogbo e se nlo,edumare o ni je ko baaje lori ti wa bi o se baaje loori awon babanla wa.

Older Posts